Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Wells

53 ẹsẹ · 43 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Obìnrin náà wí fún un pé, “Alàgbà, ìwọ kò ní igbá-ìfami tí ìwọ ó fi fà omi, bẹ́ẹ̀ ni kànga náà jì, Níbo ni ìwọ ó ti rí omi ìyè náà?

  2. Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá mu nínú omi tí èmi ó fi fún un, òǹgbẹ kì yóò gbẹ ẹ́ mọ́ láé; ṣùgbọ́n omi tí èmi ó fi fún un yóò di kànga omi nínú rẹ̀, tí yóò máa sun si ìyè àìnípẹ̀kun.”

  3. Àwọn wọ̀nyí ni kànga tí kò ní omi, ìkùùkuu tí ẹ̀fúùfù ń gbá kiri; àwọn ẹni tí a pa òkùnkùn biribiri mọ́ dè títí láé.