Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Watchman: On towers

11 ẹsẹ · 4 abala

Àwọn ẹsẹ nípa On towers

  1. Nígbà tí olùṣọ́ kan tí ó dúró ní ilé ìṣọ́ ní Jesreeli, rí ọ̀wọ́ ogun Jehu tí wọ́n ń súnmọ́ tòsí, ó pè jáde, “Mo rí àwọn ọ̀wọ́ ogun tí ó ń bọ̀.” “Mú ọkùnrin ẹlẹ́ṣin kan,” Joramu pa á láṣẹ. “Rán an lọ sí ọ̀dọ̀ wọn kí o sì béèrè pé, ‘Ṣé ẹ̀yin wá pẹ̀lú àlàáfíà?’ ”

  2. Nígbà tí àwọn ènìyàn Juda jáde sí ìhà ilé ìṣọ́ ní aginjù, wọn ń wo àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn, òkú nìkan ni wọ́n rí tí ó ṣubú sí ilẹ̀, kò sì sí ẹnìkan tí ó rí ààyè sá.

  3. Wọ́n tẹ́ tábìlì, wọ́n tẹ́ ẹní àtẹ́ẹ̀ká, wọ́n jẹ, wọ́n mu! Dìde nílẹ̀, ẹ̀yin ọmọ-aládé, ẹ fi òróró kún asà yín!

  4. Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún mi: “Lọ, kí o bojúwòde kí o sì wá sọ ohun tí ó rí.

  5. Nígbà tí ó bá rí àwọn kẹ̀kẹ́ ogun àti àkójọpọ̀ àwọn ẹṣin, àwọn tó ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tàbí àwọn tí ó gun ìbákasẹ, jẹ́ kí ó múra sílẹ̀, àní ìmúra gidigidi.”

  6. Òun sì kígbe pé, kìnnìún kan, “Láti ọjọ́ dé ọjọ́, olúwa mi, mo dúró lórí ilé ìṣọ́ ní ọ̀sán, a sì fi mí ìṣọ́ mi ní gbogbo òru.

  7. Wò ó, ọkùnrin kan ni ó ń bọ̀ wá yìí nínú kẹ̀kẹ́ ogun àti àkójọpọ̀ àwọn ẹṣin. Ó sì mú ìdáhùn padà wá: ‘Babeli ti ṣubú, ó ti ṣubú! Gbogbo àwọn ère òrìṣà rẹ̀ ló fọ́nká sórí ilẹ̀!’ ”

  8. Ẹ̀yin ènìyàn mi, tí a gún mọ́lẹ̀ ní ilẹ̀ ìpakà, mo sọ ohun tí mo ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun, láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Israẹli.

  9. Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Dumahi. Ẹnìkan ké sí mi láti Seiri wá, “Alóre, kí ló kù nínú òru náà?”

  10. Alóre náà dáhùn wí pé, “Òwúrọ̀ súnmọ́ tòsí, àti òru náà pẹ̀lú. Bí ìwọ yóò bá béèrè, béèrè; kí o sì tún padà wá.”

  11. Ọjọ́ kan máa wà tí àwọn olùṣọ́ yóò kígbe jáde lórí òkè Efraimu wí pé, ‘Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a gòkè lọ sí Sioni, ní ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run wa.’ ”