Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Vine: Symbolic

5 ẹsẹ · 5 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Symbolic

  1. “Èmi ni àjàrà tòótọ́, Baba mi sì ni olùṣọ́gbà.

  2. Gbogbo ẹ̀ka nínú mi tí kò bá so èso, òun a mú kúrò, gbogbo ẹ̀ka tí ó bá sì so èso, òun a wẹ̀ ẹ́ mọ́, kí ó lè so èso sí i.

  3. Ẹ̀yin mọ́ nísinsin yìí nítorí ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ fún yín.

  4. Ẹ máa gbé inú mi, èmi ó sì máa gbé inú yín. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka kò ti lè so èso fún ara rẹ̀ bí kò ṣe pé ó ba ń gbé inú àjàrà, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin, bí kò ṣe pé ẹ bá ń gbé inú mi.

  5. “Èmi ni àjàrà, ẹ̀yin ni ẹ̀ka. Ẹni tí ó ń gbé inú mi, àti èmi nínú rẹ̀, òun ni yóò so èso lọ́pọ̀lọ́pọ̀, nítorí ní yíya ara yín kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ kò lè ṣe ohun kan.