Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Uriel
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Tahati ọmọkùnrin rẹ̀, Urieli ọmọkùnrin rẹ̀, Ussiah ọmọkùnrin rẹ̀ àti Saulu ọmọkùnrin rẹ̀.
Ọgọ́fà nínú àwọn ọmọ Kohati; Urieli olórí àti àwọn ẹbí rẹ̀.
Dafidi sì ránṣẹ́ pe Sadoku, Abiatari tí wọ́n jẹ́ àlùfáà, àti Urieli, Asaiah. Joẹli, Ṣemaiah, Elieli àti Amminadabu tí wọ́n jẹ́ Lefi.
Ó sì fi fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni olórí àwọn ìdílé Lefi; ẹ̀yin àti àwọn Lefi ènìyàn yín, ẹ ya ara yín sí mímọ́ kí ẹ lè gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, lọ sí ibi tí mó ti pèsè sílẹ̀ fún un.
Ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́ta. Orúkọ ìyá rẹ̀ a máa jẹ́ Mikaiah, ọmọbìnrin Urieli ti Gibeah. Ogun wà láàrín Abijah àti Jeroboamu.