Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Under the Law Atonement

34 ẹsẹ · 19 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. “Finehasi ọmọ Eleasari ọmọ Aaroni, àlùfáà, ti yí ìbínú mi padà kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli, nítorí tí ó ní ìtara bí èmi náà ti ní ìtara fún iyì mi láàrín wọn, kí ó lè jẹ́ pé èmi ló pa wọ́n run nínú ìtara mi sí wọn.

  2. Nítorí náà sọ fún un pé èmi ṣe májẹ̀mú àlàáfíà mi pẹ̀lú rẹ̀.

  3. Òun àti irú-ọmọ rẹ̀ yóò ní májẹ̀mú láéláé fún iṣẹ́ àlùfáà, nítorí pé ó ní ìtara fún Ọlọ́run rẹ̀ láti fi yẹ́ Ọlọ́run sí, ó sì ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Israẹli.”

  4. Nítorí ìgbà tí àwa jẹ́ aláìlera, ní àkókò tí ó yẹ, Kristi kú fún àwa aláìwà-bí-Ọlọ́run.

  5. Nítorí ó ṣọ̀wọ́n kí ẹnìkan tó kú fún olódodo, ṣùgbọ́n fún ènìyàn rere bóyá ẹlòmíràn tilẹ̀ lè dábàá láti kú.

  6. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi ìfẹ́ òun pàápàá sí wa hàn nínú èyí pé, nígbà tí àwa jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa.

  7. Mélòó mélòó sì ni tí a dá wa láre nísinsin yìí nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ni a ó gbà wá là kúrò nínú ìbínú nípasẹ̀ rẹ̀.

  8. Ǹjẹ́, nígbà tí àwa wà ní ọ̀tá, a mú wa, ba Ọlọ́run làjà nípa ikú Ọmọ rẹ̀, mélòó mélòó, nígbà tí a là wá ní ìjà tan, ni a ó gbà wá là nípa ìyè rẹ̀.

  9. Kì sì í ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n àwa ń ṣògo nínú Ọlọ́run nípa Olúwa wa Jesu Kristi, nípasẹ̀ ẹni tí àwa ti rí ìlàjà gbà nísinsin yìí.