Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Trespass: Of an ox

9 ẹsẹ · 4 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Of an ox

  1. “Bí akọ màlúù bá kan ọkùnrin tàbí obìnrin kan pa, a ó sọ akọ màlúù náà ní òkúta pa, a kò sì gbọdọ̀ jẹ ẹran rẹ̀. Ṣùgbọ́n a kò ní dá ẹni tí ó ni akọ màlúù náà lẹ́bi, ọrùn oní akọ màlúù náà yóò sì mọ́.

  2. Ṣùgbọ́n tí ó bá ti di ìgbà gbogbo ti akọ màlúù náà ti máa ń kan ènìyàn, tí a sì ti ń kìlọ̀ fún olówó rẹ̀, ti olówó rẹ̀ kò sì mú un so, tí ó bá kan ọkùnrin tàbí obìnrin pa, a ó sọ akọ màlúù náà ní òkúta pa, a ó sì pa olówó rẹ̀ pẹ̀lú.

  3. Bí àwọn ará ilé ẹni tí ó kú bá béèrè fún owó ìtánràn, yóò san iye owó tí wọ́n bá ní kí ó san fún owó ìtánràn láti fi ra ẹ̀mí ara rẹ̀ padà.

  4. Bí akọ màlúù bá kan ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin pa, a ó ṣe gẹ́gẹ́ bí òfin yìí ti là á kalẹ̀.

  5. Bí akọ màlúù bá kan ẹrúkùnrin tàbí ẹrúbìnrin pa, olówó rẹ̀ yóò san ọgbọ̀n ṣékélì fàdákà fún ẹni tó ni ẹrú, a ó sì sọ akọ màlúù náà ni òkúta pa.

  6. “Bí ọkùnrin kan bá ṣí kòtò sílẹ̀ láìbò tàbí kí ó gbẹ́ kòtò sílẹ̀ láìbò, tí màlúù tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ bá ṣe bẹ́ẹ̀ bọ́ sínú kòtò náà.

  7. Ẹni tí ó ni kòtò yóò san owó àdánù yìí fún ẹni tí ó ni ẹran. Òkú ẹran náà yóò sì di tirẹ̀.

  8. “Bí akọ màlúù ọkùnrin kan bá pa akọ màlúù ẹlòmíràn lára tí ó sì kú, wọn yóò ta akọ màlúù tó wà láààyè, wọn yóò sì pín owó èyí tiwọn tà àti ẹran èyí tí ó kú dọ́gbadọ́gba.

  9. Ṣùgbọ́n tí ó bá ti di ìgbà gbogbo tí akọ màlúù náà máa ń kan òmíràn, tí olówó rẹ̀ kò sì mú un so, olówó rẹ̀ yóò san ẹran dípò ẹran. Ẹran tí ó kú yóò sì jẹ́ tirẹ̀.