Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Theocracy

18 ẹsẹ · 2 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì pa ohùn wọn pọ̀ wọ́n sì dáhùn wí pé, “Àwa yóò ṣe ohun gbogbo ti Olúwa wí.” Mose sì mú ìdáhùn wọn padà tọ Olúwa lọ.

  2. Nígbà ti Mose lọ láti sọ fún àwọn ènìyàn, gbogbo ọ̀rọ̀ àti òfin Olúwa, wọ́n wí ní ohùn kan pé, “Gbogbo ohun ti Olúwa wí ni àwa yóò ṣe.”

  3. Nígbà náà ni ó sì mú ìwé májẹ̀mú, ó sì kà á sí àwọn ènìyàn. Wọ́n dáhùn pé, “Àwa yóò ṣe gbogbo ohun tí Olúwa wí. Àwa yóò sì gbọ́rọ̀.”

  4. Ṣùgbọ́n èéṣe tí àwa yóò fi kú? Iná ńlá yìí yóò jó wa run, bí àwa bá sì tún gbọ́ ohun Olúwa Ọlọ́run wa, àwa ó kú.

  5. Ta ni nínú ẹlẹ́ran ara tí ó ti gbọ́ ohun Ọlọ́run alààyè láti inú iná rí, bí àwa ti gbọ́ ọ, tí a sì wà láyé?

  6. Súnmọ́ tòsí ibẹ̀ kí o sì gbọ́ gbogbo ohun tí Olúwa Ọlọ́run wa yóò sọ, nígbà náà sọ ohunkóhun tí Olúwa Ọlọ́run wa sọ fún ọ fún wa. A ó sì fetísílẹ̀, a ó sì gbọ́rọ̀.”

  7. Olúwa ń gbọ́ nígbà tí ẹ̀yin ń bá mi sọ̀rọ̀, Olúwa sì sọ fún mi pé, “Mo ti gbọ́ ohun tí àwọn ènìyàn yí sọ fún ọ. Gbogbo ohun tí wọ́n sọ dára,

  8. ìbá ti dára tó, bí ọkàn wọn bá lè bẹ̀rù mi, tí ó sì ń pa gbogbo òfin mi mọ́ nígbà gbogbo, kí ó bá à lè dára fún wọn, àti àwọn ọmọ wọn láéláé.

  9. Ó sì wí pé, “Olúwa ti Sinai wá, ó sì yọ sí wọn láti Seiri wá ó sì tàn án jáde láti òkè Parani wá. Ó ti ọ̀dọ̀ ẹgbẹgbàarùn-ún àwọn mímọ́ wá láti ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ni òfin kan a mú bí iná ti jáde fún wọn wá.

  10. Nítòótọ́, ó fẹ́ràn àwọn ènìyàn an rẹ̀, gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ wà ní ọwọ́ rẹ̀. Ní ẹsẹ̀ rẹ̀ ni wọ́n ti foríbalẹ̀, àti lọ́dọ̀ rẹ̀ ni wọ́n ti ń gba ọ̀rọ̀,

  11. òfin tí Mose fi fún wa, ìní ti ìjọ ènìyàn Jakọbu.

  12. Òun ni ọba lórí Jeṣuruni ní ìgbà tí olórí àwọn ènìyàn péjọpọ̀, pẹ̀lú àwọn ẹ̀yà Israẹli.

  13. Ṣùgbọ́n Gideoni dá wọn lóhùn pé, “Èmi kì yóò jẹ ọba lórí yín, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ mi kì yóò jẹ ọba lórí yín. Olúwa ni yóò jẹ ọba lórí yín.”

  14. Olúwa sì sọ fún Samuẹli pé, “Gbọ́ ohùn àwọn ènìyàn náà, ní gbogbo èyí tí wọ́n sọ fún ọ; nítorí kì í ṣe ìwọ ni wọ́n kọ̀, ṣùgbọ́n èmi ni wọ́n kọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba lórí wọn.

  15. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà kọ̀ láti tẹ́tí sí Samuẹli wọ́n wí pé, “Rárá! A bí ìwọ fẹ́ jẹ́ ọba lórí i wa?

  16. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti kọ Ọlọ́run yín, tí ó gbà yín kúrò nínú gbogbo wàhálà àti ìpọ́njú yín. Ẹ̀yin sì ti sọ pé, ‘Rárá, yan ọba kan fún wa.’ Báyìí, ẹ kó ara yín jọ níwájú Olúwa ní ẹ̀yà àti ìdílé yín.”

  17. “Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀yin sì rí i pé Nahaṣi ọba àwọn Ammoni dìde sí i yín, ẹ sọ fún mi pé, ‘Rárá, àwa ń fẹ́ ọba tí yóò jẹ́ lórí wa,’ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa Ọlọ́run yín jẹ́ ọba yín.

  18. “Nísinsin yìí, ìwọ ṣètò láti kọ́ ìjọba Olúwa, tí ó wà lọ́wọ́ àwọn àtẹ̀lé Dafidi. Ìwọ jẹ́ ọmọ-ogun tí ó gbilẹ̀, ìwọ sì ní pẹ̀lú rẹ ẹgbọrọ màlúù wúrà ti Jeroboamu dà láti fi ṣe Ọlọ́run yín.