Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Ostrich
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
“ ‘Àwọn ẹyẹ wọ̀nyí ni ẹ gbọdọ̀ kórìíra tí ẹ kò gbọdọ̀ jẹ wọ́n torí pé ohun ìríra ni wọ́n: idì, oríṣìíríṣìí igún,
Èmi ti di arákùnrin ìkookò, èmi di ẹgbẹ́ àwọn ògòǹgò.
“Ìwọ ni yóò ha fi ìyẹ́ dáradára fún ọ̀kín bí, tàbí ìyẹ́ àti ìhùhù bo ògòǹgò?
Ó yé ẹ̀yìn rẹ̀ sílẹ̀ lórí ilẹ̀, a sì mú wọn gbóná nínú ekuru;
tí ó sì gbàgbé pé, ẹsẹ̀ lè tẹ̀ wọ́n fọ́, tàbí pé ẹranko igbó lè tẹ̀ wọ́n fọ́.
Kò ní àánú sí àwọn ọmọ rẹ̀ bí ẹni pé wọn kì í ṣe tirẹ̀; asán ni iṣẹ́ rẹ̀ láìní ìbẹ̀rù;
nítorí pé Ọlọ́run kò fún un ní ọgbọ́n, bẹ́ẹ̀ ni kò sì fi ìpín òye fún un.
Nígbà tí ó gbé ara sókè, ó gan ẹṣin àti ẹlẹ́ṣin.
Àwọn ajáko pèsè ọmú wọn fún ìtọ́jú àwọn ọmọ wọn, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi wá láì lọ́kàn bí ògòǹgò ní aginjù.