Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Evening

8 ẹsẹ · 20 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. “ ‘Nípa àwọn wọ̀nyí ni ẹ le fi sọ ara yín di àìmọ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan òkú wọn yóò di aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.

  2. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé òkú wọn gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, yóò sì jẹ́ aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.

  3. “ ‘Àwọn ẹranko tí pátákò wọn kò là tan tàbí tí wọn kò jẹ àpọ̀jẹ jẹ́ àìmọ́ fún yín. Ẹni tí ó bá fọwọ́ kan òkú èyíkéyìí nínú wọn yóò jẹ́ aláìmọ́.

  4. Nínú gbogbo ẹranko tí ń fi ẹsẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn, àwọn tí ń fi èékánná wọn rìn jẹ́ aláìmọ́ fún yín, ẹni tí ó bá fọwọ́ kan òkú wọn yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

  5. Ẹni tí ó bá gbé òkú wọn gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, yóò sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Wọ̀nyí jẹ́ àìmọ́ fún yín.

  6. Bí ẹnikẹ́ni bá fi ara kan ibùsùn rẹ̀, ó gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀. Yóò sì wà ní ipò àìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.

  7. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jókòó lórí ohunkóhun tí ọkùnrin tí ó ní ìsunjáde bá jókòó le gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, kí ó sì wà láìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

  8. “ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan ọkùnrin náà tí ó ní ìsunjáde gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóò sì di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.