Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Sibmah: A city of Reuben

4 ẹsẹ · 3 abala

Àwọn ẹsẹ nípa A city of Reuben

  1. Kiriataimu, Sibma, Sereti Ṣahari lórí òkè ní àfonífojì.

  2. Gbogbo pápá oko Heṣboni ti gbẹ, bákan náà ni àjàrà Sibma rí. Àwọn aláṣẹ àwọn orílẹ̀-èdè wọ́n tẹ àwọn àyànfẹ́ àjàrà mọ́lẹ̀, èyí tí ó ti fà dé Jaseri ó sì ti tàn dé agbègbè aginjù. Àwọn èhíhù rẹ̀ fọ́n jáde, ó sì lọ títí ó fi dé Òkun.

  3. Nítorí náà mo sọkún, gẹ́gẹ́ bí Jaseri ṣe sọkún, fún àwọn àjàrà Sibma. Ìwọ Heṣboni, ìwọ Eleale, mo bomirin ọ́ pẹ̀lú omi ojú! Igbe ayọ̀ lórí àwọn èso pípọ́n rẹ àti lórí ìkórè èyí tí o ti mọ́wọ́ dúró.

  4. Mo sọkún fún ọ bí Jaseri ṣe sọkún ìwọ àjàrà Sibma. Ẹ̀ka rẹ tẹ̀ títí dé Òkun, wọn dé Òkun Jaseri. Ajẹnirun ti kọlu èso rẹ, ìkórè èso àjàrà rẹ.