Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Shelemiah

10 ẹsẹ · 8 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Kèké fún ẹnu-ọ̀nà ilà oòrùn bọ́ sí ọ̀dọ̀ Ṣelemiah. Nígbà náà a dá kèké fún ọmọkùnrin rẹ̀ Sekariah, ọlọ́gbọ́n onímọ̀ràn, kèké fún ẹnu-ọ̀nà àríwá sì bọ́ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀.

  2. Ṣelemiah, Natani, Adaiah,

  3. Asareeli, Ṣelemiah, Ṣemariah,

  4. Lẹ́yìn rẹ̀ ni, Hananiah ọmọ Ṣelemiah, àti Hanuni ọmọ ẹ̀kẹfà Salafi, tún apá ibòmíràn ṣe. Lẹ́yìn wọn ni, Meṣullamu ọmọ Berekiah tún ọ̀kánkán òdìkejì ibùgbé ẹ̀ ṣe.

  5. Mo sì fi àlùfáà Ṣelemiah, Sadoku akọ̀wé àti ọmọ Lefi kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Pedaiah ṣe alákòóso àwọn yàrá ìkó nǹkan pamọ́ sí. Mo sì yan Hanani ọmọ Sakkuri, ọmọ Mattaniah bí olùrànlọ́wọ́ ọ wọn. Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ni a kà sí àwọn tó ṣé e gbẹ́kẹ̀lé. Àwọn ni a yàn láti máa pín ohun èlò fún àwọn arákùnrin wọn.

  6. Gbogbo àwọn ìjòyè sì rán Jehudu ọmọ Netaniah ọmọ Ṣelemiah ọmọ Kuṣi sí Baruku wí pé, mú ìwé kíká náà ní ọwọ́ rẹ láti inú èyí tí ìwọ kà ní etí àwọn ènìyàn; kí o si wá. Nígbà náà ni Baruku ọmọ Neriah wá sí ọ̀dọ̀ wọn pẹ̀lú ìwé kíká ní ọwọ́ rẹ̀.

  7. Dípò èyí ọba pàṣẹ fún Jerahmeeli ọmọ Hameleki, Seraiah ọmọ Asrieli àti Ṣelemiah ọmọ Abdeeli láti mú Baruku akọ̀wé àti Jeremiah wòlíì ṣùgbọ́n Olúwa fi wọ́n pamọ́.

  8. Sedekiah ọba sì rán Jehukali ọmọ Ṣelemiah àti Sefaniah ọmọ Maaseiah sí Jeremiah wòlíì wí pé, “Jọ̀wọ́ gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run wa fún wa.”

  9. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n dé ẹnu ibodè Benjamini, olórí àwọn olùṣọ́ tí orúkọ rẹ ń jẹ́ Irijah ọmọ Ṣelemiah ọmọ Hananiah mú un, ó wí pé, “Ìwọ ń fi ara mọ́ àwọn ará Babeli.”

  10. Ṣefatia ọmọ Mattani, Gedaliah ọmọ Paṣuri, Jehukali ọmọ Ṣelemiah, àti Paṣuri ọmọ Malkiah, gbọ́ ohun tí Jeremiah ń sọ fún àwọn ènìyàn nígbà tí ó sọ wí pé,