Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Reconciliation With God: By the death of Christ
Àwọn ẹsẹ nípa By the death of Christ
Ǹjẹ́, nígbà tí àwa wà ní ọ̀tá, a mú wa, ba Ọlọ́run làjà nípa ikú Ọmọ rẹ̀, mélòó mélòó, nígbà tí a là wá ní ìjà tan, ni a ó gbà wá là nípa ìyè rẹ̀.
àti kí ó lè mú àwọn méjèèjì bá Ọlọ́run làjà nínú ara kan nípa àgbélébùú; nípa èyí tí yóò fi pa ìṣọ̀tá náà run.
Ẹ̀yin ya ara yín nípá kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run nígbà kan rí, ẹ jẹ́ ọ̀tá nínú ọkàn yín nítorí ìwà búburú yín.
Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ó ti bá yín làjà nípa ara Kristi nípa ikú láti mú un yín lọ sí iwájú rẹ̀ ní mímọ́, aláìlábàwọ́n àti kúrò nínú ìdálẹ́bi,