Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Quickening of the Church: By the Holy Spirit
Àwọn ẹsẹ nípa By the Holy Spirit
Ẹ̀mí ní ń sọ ni di ààyè; ara kò ní èrè kan; ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí mo sọ fún yín, ẹ̀mí ni, ìyè sì ni pẹ̀lú.
Àti pé, bí ẹ̀mí Ọlọ́run, ẹni tí ó jí Jesu kúrò nínú òkú bá ń gbé inú yín, ẹni tí ó jí Kristi Jesu dìde kúrò nínú òkú, yóò fi ẹ̀mí rẹ̀ tí ń gbé inú yín sọ ara kíkú yín di ààyè pẹ̀lú.
Ẹni tí ó mú wa yẹ bí ìránṣẹ́ májẹ̀mú tuntun; kì í ṣe ní ti ìwé àkọsílẹ̀ ṣùgbọ́n ní ti ẹ̀mí, nítorí ìwé a máa pa ni, ṣùgbọ́n ẹ̀mí a máa sọ ní di ààyè.
Nítorí tí Kristi pẹ̀lú jìyà lẹ́ẹ̀kan nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, olóòótọ́ fún àwọn aláìṣòótọ́, kí a lè mú wa dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí a pa nínú ara, ṣùgbọ́n tí a sọ di ààyè nínú ẹ̀mí.