Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Pharisees: Become disciples of Jesus
Àwọn ẹsẹ nípa Become disciples of Jesus
Ọkùnrin kan sì wà nínú àwọn Farisi, tí a ń pè ní Nikodemu, ìjòyè kan láàrín àwọn Júù.
Ṣùgbọ́n àwọn kan nínú ẹ̀yà àwọn Farisi tí wọ́n gbàgbọ́ dìde, wọ́n ń wí pé, “A ní láti kọ wọ́n ní ilà, àti láti pàṣẹ fún wọn pé kí wọn máa pa òfin Mose mọ́.”
“Júù ni èmi í ṣe, a bí mi ni Tarsu ìlú kan ní Kilikia, ṣùgbọ́n tí a tọ́ mi dàgbà ni ìlú yìí. Ní abẹ́ ẹsẹ̀ Gamalieli ni a sì gbé kọ́ mi ní òfin àwọn baba wa, tí mo sì ní ìtara fún Ọlọ́run àní gẹ́gẹ́ bí gbogbo yin tí rí ni òní.