Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Pearl: General references

4 ẹsẹ · 5 abala

Àwọn ẹsẹ nípa General references

  1. A kò lè dárúkọ iyùn tàbí òkúta jasperi; iye ọgbọ́n sì ju iyùn lọ.

  2. A sì fi aṣọ elése àlùkò àti aṣọ òdòdó wọ obìnrin náà, a sì fi wúrà àti òkúta iyebíye àti perli ṣe é ní ọ̀ṣọ́, ó ní ago wúrà kan ní ọwọ́ rẹ̀, tí ó kún fún ìríra àti fún ẹ̀gbin àgbèrè rẹ̀;

  3. Ọjà wúrà, àti ti fàdákà, àti ti òkúta iyebíye, àti ti perli, àti ti aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́, àti tí elése àlùkò, àti ti ṣẹ́dà, àti ti òdòdó, àti ti gbogbo igi olóòórùn dídùn, àti ti olúkúlùkù ohun èlò tí a fi igi iyebíye ṣe, àti ti idẹ, àti ti irin, àti ti òkúta mabu.

  4. wí pé: “ ‘Ègbé! Ègbé, ni fún ìlú ńlá nì, tí a wọ̀ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́, àti ti elése àlùkò, àti ti òdòdó, àti ti a sì fi wúrà ṣe ní ọ̀ṣọ́, pẹ̀lú òkúta iyebíye àti peali!