Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Peace: Shall abound in the latter days
Àwọn ẹsẹ nípa Shall abound in the latter days
Òun ó ṣe ìdájọ́ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, yóò sì parí aáwọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn. Wọn yóò fi idà wọn rọ ọkọ́ ìtulẹ̀, wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé. Orílẹ̀-èdè kì yóò sì gbé idà sí orílẹ̀-èdè mọ́, bẹ́ẹ̀ ní wọn kì yóò kọ́ ogun jíjà mọ́.
Owú jíjẹ Efraimu yóò pòórá, àwọn ọ̀tá Juda ni a ó ké kúrò, Efraimu kò ní jowú Juda, tàbí Juda kó dojúkọ Efraimu.
Àwọn ènìyàn mi yóò máa gbé ní ibùgbé àlàáfíà, ní ibùgbé ìdánilójú, ní àwọn ibi ìsinmi tí ó parọ́rọ́.