Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Pardon: The impenitent
Àwọn ẹsẹ nípa The impenitent
Jesu sì dáhùn ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ṣe bí àwọn ará Galili wọ̀nyí ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀ ju gbogbo àwọn ará Galili lọ, nítorí wọ́n jẹ irú ìyà bá-wọ̀n-ọn-nì?
Mo wí fún yín, bí kò ṣe pé ẹ̀yin pẹ̀lú ronúpìwàdà, gbogbo yín ni yóò ṣègbé bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́.
Tàbí àwọn méjìdínlógún, tí ilé ìṣọ́ ní Siloamu wó lù, tí ó sì pa wọ́n, ẹ̀yin ṣe bí wọ́n ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀ ju gbogbo àwọn ènìyàn tí ń bẹ ní Jerusalẹmu lọ?
Mo wí fún yín, bí kò ṣe pé ẹ̀yin ronúpìwàdà, gbogbo yín ni yóò ṣègbé bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́.”