Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Nation: Peace of
Àwọn ẹsẹ nípa Peace of
Ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá dákẹ́ síbẹ̀, ta ni yóò dá lẹ́bi? Nígbà tí ó bá pa ojú rẹ̀ mọ́, ta ni yóò lè rí i? Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe si orílẹ̀-èdè tàbí sí ènìyàn kan ṣoṣo;
Ìbùkún ni fún orílẹ̀-èdè náà, Ọlọ́run ẹni tí Olúwa jẹ́ tirẹ̀, àti àwọn ènìyàn náà tí ó ti yàn ṣe ìní rẹ̀.
Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn tí wọn mọ ohùn ayọ̀ nì, Olúwa wọ́n ó máa rìn ní ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ.
Wọn ń ṣògo nínú orúkọ rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́, wọn ń yin òdodo rẹ.
Nítorí ìwọ ni ògo agbára wọn; nípa ojúrere ni ìwo wá ń ṣògo.
Nítorí ti Olúwa ni asà wa, ọba wa sì ni Ẹni Mímọ́ Israẹli.