Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Muster

5 ẹsẹ · 1 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Nígbà náà ni Saulu wí fún àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ pé, “Ẹ ka àwọn ènìyàn kí ẹ sì mọ ẹni tí ó jáde kúrò nínú wa.” Nígbà tí wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀, sì wò ó, Jonatani àti ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ ni kò sì sí níbẹ̀.

  2. Ọba sì wí fún Amasa pé, “Pe àwọn ọkùnrin Juda fún mi ní ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́ta òní, kí ìwọ náà kí o sì wà níhìn-ín yìí.”

  3. Ó sì ṣe ní àmọ́dún, Beni-Hadadi ka iye àwọn ará Aramu, ó sì gòkè lọ sí Afeki, láti bá Israẹli jagun.

  4. Àti àwọn tí ó kù ní ìlú, ó mú ìwẹ̀fà kan tí ó fi se olórí àwọn ológun, àti ọkùnrin márùn-ún nínú àwọn tó ń gba ọba ní ìmọ̀ràn. Ó sì tún mú akọ̀wé olórí ogun, tí ó ń to àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà àti ọgọ́ta nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ tí wọ́n rí ní ìlú.

  5. Gbọ́ ohùn kan ní àwọn orí òkè, gẹ́gẹ́ bí i ti ogunlọ́gọ̀ ènìyàn. Gbọ́ ìdàrúdàpọ̀ láàrín àwọn ìjọba, gẹ́gẹ́ bí i ti ìkórajọ àwọn orílẹ̀-èdè! Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti kó ogun rẹ̀ jọ àwọn jagunjagun fún ogun.