Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Michal: Ridicules David on account of his religious zeal

5 ẹsẹ · 5 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Ridicules David on account of his religious zeal

  1. Bí àpótí ẹ̀rí Olúwa sì ti wọ ìlú Dafidi wá; Mikali ọmọbìnrin Saulu sì wo láti ojú fèrèsé, ó sì rí Dafidi ọba ń fò sókè ó sì ń jó níwájú Olúwa; òun sì kẹ́gàn rẹ̀ ní ọkàn rẹ̀.

  2. Dafidi sì yípadà láti súre fún àwọn ará ilé rẹ̀, Mikali ọmọbìnrin Saulu sì jáde láti wá pàdé Dafidi, ó sì wí pé, “Báwo ni ọba Israẹli ṣe ṣe ara rẹ̀ lógo bẹ́ẹ̀ lónìí, tí ó bọ́ ara rẹ̀ sílẹ̀ lónìí lójú àwọn ìránṣẹ́bìnrin àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn lásán tí ń bọ́ra rẹ̀ sílẹ̀.”

  3. Dafidi sì wí fún Mikali pé, “Níwájú Olúwa ni, ẹni tí ó yàn mí fẹ́ ju baba rẹ lọ, àti ju gbogbo ìdílé rẹ lọ, láti fi èmi ṣe olórí àwọn ènìyàn Olúwa, àní lórí Israẹli, èmi ó sì súre níwájú Olúwa.

  4. Èmi ó sì tún rẹ ara mi sílẹ̀ jú bẹ́ẹ̀ lọ, èmi ó sì ṣe aláìníyìn lójú ara mi, àti lójú àwọn ìránṣẹ́bìnrin náà ti ìwọ wí, lọ́dọ̀ wọn náà ni èmi ó sì ní ògo.”

  5. Mikali ọmọbìnrin Saulu kò sì bí ọmọ, títí o fi di ọjọ́ ikú rẹ̀ nítorí tí ó sọ̀rọ̀-òdì yìí sí Dafidi.