Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Leaven

9 ẹsẹ · 14 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Fún ọjọ́ méje ni ẹ̀yin yóò fi jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, ẹ ó gbé ìwúkàrà kúrò ni ilé yín, nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ohunkóhun tí ó ni ìwúkàrà nínú láti ọjọ́ kìn-ín-ní di ọjọ́ keje ni kí a yọ kúrò ni Israẹli.

  2. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní kí àpéjọ mímọ́ kí ó wà; àti ní ọjọ́ keje àpéjọ mímọ́ mìíràn yóò wà fún yín. Ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ kan ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, bí kò ṣe oúnjẹ tí olúkúlùkù yóò jẹ; kìkì èyí ni gbogbo ohun tí ẹ̀yin lè ṣe.

  3. “Ẹ ó sì kíyèsí àjọ àìwúkàrà, nítorí ní ọjọ́ náà gan an ni mo mú ogun yín jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti. Nítorí náà ni kí ẹ máa kíyèsi ọjọ́ náà ní ìran-ìran yín bí ìlànà tí yóò wà títí ayé.

  4. Àkàrà ti kò ni ìwúkàrà ni ẹ̀yin yóò jẹ láti ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹrìnlá títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kọ̀kànlélógún oṣù àkọ́kọ́.

  5. Fún ọjọ́ méje ni ẹ kò gbọdọ̀ ni ìwúkàrà nínú ilé yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ohun tí ó ni ìwúkàrà nínú ni a ó yọ kúrò ni àárín àwùjọ Israẹli, ìbá à ṣe àlejò tàbí ẹni tí a bí ní ilẹ̀ náà.

  6. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ohunkóhun tí a fi ìwúkàrà ṣe. Ní ibikíbi tí ẹ̀yin bá ń gbé, kí ẹ̀yin kí ó jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà.”

  7. Ìṣeféfé yín kò dára. Ẹ̀yin kò mọ̀ pé ìwúkàrà díẹ̀ ní mú gbogbo ìyẹ̀fun di wíwú?

  8. Nítorí náà ẹ mú ìwúkàrà àtijọ́ kúrò nínú yín, kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ ìyẹ̀fun tuntun, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin tí jẹ àkàrà ti kò ní ìwúkàrà. Nítorí à ti fi ìrékọjá wa, àní Kristi ni a ti pa láti fi ṣe ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ wa.

  9. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á pa àjọ náà mọ́, kì í ṣe pẹ̀lú ìwúkàrà àtijọ́ bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pẹ̀lú ìwúkàrà àrankàn àti ìwà búburú, ṣùgbọ́n pẹ̀lú àkàrà tí kò ní ìwúkàrà, àkàrà òtítọ́ àti òdodo.