Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Lamb

10 ẹsẹ · 2 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. “Èyí ni ìwọ yóò máa fi rú ẹbọ ní orí pẹpẹ náà: Ọ̀dọ́-àgùntàn méjì ọlọ́dún kan ni ojoojúmọ́ láéláé.

  2. Ọ̀dọ́-àgùntàn kan ni ìwọ yóò fi rú ẹbọ ní òwúrọ̀ àti ọ̀dọ́-àgùntàn èkejì ní àṣálẹ́.

  3. Pẹ̀lú ọ̀dọ́-àgùntàn ti àkọ́kọ́ rú ẹbọ ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun dídára tí a fi ìdámẹ́rin hínì òróró lára olifi tí a gún, àti ìdámẹ́rin hínì wáìnì bí ẹbọ mímu.

  4. Ọ̀dọ́-àgùntàn kejì ni kí ìwọ kí ó pa rú ẹbọ ní àṣálẹ́ ìwọ yóò sì ṣe sí í gẹ́gẹ́ bí ẹbọ jíjẹ àti ẹbọ mímu bí ti òwúrọ̀ fún òórùn dídùn, ẹbọ tí a fi iná ṣe ni sí Olúwa.

  5. Sọ fún wọn, ‘Èyí ní ọrẹ ẹbọ tí a fi iná sun tí ẹ gbọdọ̀ mú wá fún Olúwa: akọ ọ̀dọ́-àgùntàn méjì ọlọ́dún kan aláìlábàwọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun ní ojoojúmọ́.

  6. Pèsè ọ̀dọ́-àgùntàn kan ní òwúrọ̀ àti òmíràn ní àfẹ̀mọ́júmọ́.

  7. Pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ tí ó jẹ́ ìdámẹ́wàá efa ìyẹ̀fun dáradára tí a pò mọ́ ìdámẹ́rin hínì òróró tí a yọ lára Olifi.

  8. Èyí ni ẹbọ sísun gbogbo ìgbà tí a fi lélẹ̀ ní òkè Sinai gẹ́gẹ́ bí olóòórùn dídùn ẹbọ tí a fi iná sun fún Olúwa pẹ̀lú iná.

  9. Àfikún ọrẹ ohun mímu rẹ gbọdọ̀ jẹ́ ìdámẹ́rin ti hínì dídé omi mímu tí ó kan pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀dọ́-àgùntàn. Da ẹbọ mímu náà síta sí Olúwa ní ibi mímọ́.

  10. Pèsè ọ̀dọ́-àgùntàn kejì ní àfẹ̀mọ́júmọ́, pẹ̀lú oríṣìí ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu èyí tí ó pèsè ní òwúrọ̀, èyí ni ẹbọ tí a fi iná ṣe, olóòórùn dídùn sí Olúwa.