Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Hypocrites: Worship of, not acceptable to God

8 ẹsẹ · 43 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Worship of, not acceptable to God

  1. “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹbọ yín kín ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹbọ yín jásí fún mi?” ni Olúwa wí. “Mo ti ní ànító àti àníṣẹ́kù ẹbọ sísun ti àgbò àti ọ̀rá ẹran àbọ́pa, Èmi kò ní inú dídùn nínú ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù, ti àgùntàn àti ti òbúkọ.

  2. Nígbà tí ẹ wá farahàn níwájú mi, ta ni ó béèrè èyí lọ́wọ́ yín, gìrì gìrì ẹsẹ̀ nínú àgbàlá mi?

  3. Ẹ má mú ọrẹ asán wá mọ́! Ìríra ni tùràrí yín jásí fún mi, oṣù tuntun àti ọjọ́ ìsinmi àti àwọn àpéjọ, Èmi kò lè faradà á, ẹ̀ṣẹ̀ ni àpéjọ yín wọ̀nyí.

  4. Ayẹyẹ oṣù tuntun yín àti àjọ̀dún tí a yàn, ni ọkàn mi kórìíra. Wọ́n ti di àjàgà sí mi ní ọrùn, Ó sú mi láti fi ara dà wọ́n.

  5. Nígbà tí ẹ bá tẹ́ ọwọ́ yín sókè ni àdúrà, Èmi yóò fi ojú mi pamọ́ fún un yín, kódà bí ẹ bá gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àdúrà, Èmi kò ni tẹ́tí sí i. “Ọwọ́ yín kún fún ẹ̀jẹ̀.

  6. Wọ́n wí pé, ‘Èéṣe tí àwa fi ń gbààwẹ̀, tí ìwọ kò sì tí ì rí? Èéṣe tí àwa fi rẹra wa sílẹ̀, tí ìwọ kò sì tí ì ṣe àkíyèsí?’ “Síbẹ̀síbẹ̀ ní ọjọ́ àwẹ̀ yín, ẹ̀yin ń ṣe bí ó ti wù yín ẹ sì ń pọ́n àwọn òṣìṣẹ́ yín gbogbo lójú.

  7. Àwẹ̀ yín sì parí nínú ìjà àti asọ̀, àti lílu ọmọnìkejì ẹni pa pẹ̀lú ìkùùkuu. Ẹ̀yin kò le è gbààwẹ̀ bí ẹ ti ń ṣe lónìí kí ẹ sì retí kí a gbọ́ ohùn un yín ní ibi gíga.

  8. Ǹjẹ́ èyí ha ni irú àwẹ̀ tí mo yàn bí, ọjọ́ kan ṣoṣo fún ènìyàn láti rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀? Ó ha jẹ pe kí ènìyàn tẹ orí rẹ̀ ba bí i koríko lásán ni bí àti sísùn nínú aṣọ ọ̀fọ̀ àti eérú? Ṣé ohun tí ẹ̀ ń pè ní àwẹ̀ nìyí, ọjọ́ ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa?