Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Hunger
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Lẹ́yìn tí Òun ti gbààwẹ̀ ní ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, ebi sì ń pa á.
Nígbà náà ni olùdánwò tọ̀ ọ́ wá, ó wí pé, “Bí ìwọ bá ṣe Ọmọ Ọlọ́run, pàṣẹ kí òkúta wọ̀nyí di àkàrà.”
Ṣùgbọ́n Jesu dáhùn pé, “A ti kọ ìwé rẹ̀ pé: ‘Ènìyàn kì yóò wà láààyè nípa àkàrà nìkan, bí kò ṣe nípa gbogbo ọ̀rọ̀ ti ó ti ẹnu Ọlọ́run jáde wá.’ ”
Ogójì ọjọ́ ni a fi dán an wò lọ́wọ́ èṣù. Kò sì jẹ ohunkóhun ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì: nígbà tí wọ́n sì parí, lẹ́yìn náà ni ebi wá ń pa á.
Èṣù sì wí fún un pé, “Bí ìwọ bá ṣe Ọmọ Ọlọ́run, pàṣẹ fún òkúta yìí kí ó di àkàrà.”
Jesu sì dáhùn, ó wí fún un pé, “A ti kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ènìyàn kì yóò wà láààyè nípa àkàrà nìkan.’ ”
Ebi kì yóò pa wọn mọ́, bẹ́ẹ̀ ni òùngbẹ kì yóò gbẹ́ wọ́n mọ́; bẹ́ẹ̀ ni oòrùn kì yóò pa wọn tàbí oorukóoru kan.
Nítorí ọ̀dọ́-àgùntàn tí ń bẹ ni àárín ìtẹ́ náà ni yóò máa ṣe olùṣọ́-àgùntàn wọn, ‘tí yóò sì máa ṣe amọ̀nà wọn sí ibi orísun omi ìyè.’ ‘Ọlọ́run yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ni ojú wọn.’ ”