Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Flesh: Symbolic, body of Christ symbolized by the bread of the holy eucharist
Àwọn ẹsẹ nípa Symbolic, body of Christ symbolized by the bread of the holy eucharist
Èmi ni oúnjẹ ìyè náà tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, bí ẹnikẹ́ni bá jẹ nínú oúnjẹ yìí, yóò yè títí láéláé, oúnjẹ náà tí èmi ó sì fi fún ni fún ìyè aráyé ni ara mi.”
Nítorí náà ni àwọn Júù ṣe ń bá ara wọn jiyàn, pé, “Ọkùnrin yìí yóò ti ṣe lè fi ara rẹ̀ fún wa láti jẹ?”
Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, bí kò ṣe pé ẹ̀yin bá jẹ ara Ọmọ Ènìyàn, kí ẹ sì mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹ̀yin kò ní ìyè nínú yin.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ara mi, tí ó bá sì mu ẹ̀jẹ̀ mi, ó ní ìyè tí kò nípẹ̀kun. Èmi o sì jí i dìde níkẹyìn ọjọ́.
Nítorí ara mi ni ohun jíjẹ nítòótọ́, àti ẹ̀jẹ̀ mi ni ohun mímu nítòótọ́.
Ẹni tí ó bá jẹ ara mi, tí ó bá sì mu ẹ̀jẹ̀ mi, ó ń gbé inú mi, èmi sì ń gbé inú rẹ̀.
Gẹ́gẹ́ bí Baba alààyè ti rán mi, tí èmi sì yè nípa Baba gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó jẹ mí, òun pẹ̀lú yóò yè nípa mi.
Èyí sì ni oúnjẹ náà tí ó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá, kì í ṣe bí àwọn baba yín ti jẹ manna, tí wọ́n sì kú, ẹni tí ó bá jẹ́ oúnjẹ yìí yóò yè láéláé.”
Nǹkan wọ̀nyí ni ó sọ nínú Sinagọgu, bí ó ti ń kọ́ni ní Kapernaumu.
Nítorí náà nígbà tí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbọ́ èyí, wọ́n wí pé, “Ọ̀rọ̀ tí ó le ni èyí; ta ní lè gbọ́ ọ?”
Nígbà tí Jesu sì mọ̀ nínú ara rẹ̀ pé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń kùn sí ọ̀rọ̀ náà, ó wí fún wọn pé, “Èyí jẹ́ ìkọ̀sẹ̀ fún yín bí?
Ǹjẹ́, bí ẹ̀yin bá sì rí i tí Ọmọ Ènìyàn ń gòkè lọ sí ibi tí ó gbé ti wà rí ń kọ́?
Ẹ̀mí ní ń sọ ni di ààyè; ara kò ní èrè kan; ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí mo sọ fún yín, ẹ̀mí ni, ìyè sì ni pẹ̀lú.