Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa False Confidence

5 ẹsẹ · 3 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Ẹ má ṣe ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn ọmọ-aládé, àní, ọmọ ènìyàn, lọ́wọ́ ẹni tí kò sí ìrànlọ́wọ́.

  2. Ẹ̀mí rẹ jáde lọ, ó padà sí erùpẹ̀, ní ọjọ́ náà gan, èrò wọn yóò di òfo.

  3. Ègbé ni fún àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti fún ìrànlọ́wọ́, tí wọn gbẹ́kẹ̀lé ẹṣin tí wọ́n fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ kẹ̀kẹ́-ẹṣin wọn àti agbára ńlá àwọn ẹlẹ́ṣin wọn, ṣùgbọ́n tiwọn kò bojú wo Ẹni Mímọ́ Israẹli n nì, tàbí kí wọn wá ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ Olúwa.

  4. Síbẹ̀síbẹ̀ òun pẹ̀lú jẹ́ ọlọ́gbọ́n ó sì lè mú ìparun wá; òun kì í kó ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ. Òun yóò dìde sí ilé àwọn ìkà, àti sí àwọn tí ń ṣe ìrànlọ́wọ́ fún aṣebi.

  5. Ṣùgbọ́n ènìyàn lásán ni àwọn ará Ejibiti wọn kì í ṣe Ọlọ́run; ẹran-ara ni àwọn ẹṣin wọn, kì í ṣe ẹ̀mí. Nígbà tí Olúwa bá na ọwọ́ rẹ̀ jáde, ẹni náà tí ó ń ṣèrànwọ́ yóò kọsẹ̀, ẹni náà tí à ń ràn lọ́wọ́ yóò ṣubú; àwọn méjèèjì yóò sì jùmọ̀ parun.