Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa False Accusation: General references

12 ẹsẹ · 1 abala

Àwọn ẹsẹ nípa General references

  1. “Ìwọ kò gbọdọ̀ tan ìròyìn èké kalẹ̀. Ìwọ kò gbọdọ̀ ran ènìyàn búburú lọ́wọ́ láti jẹ́rìí èké.

  2. Má ṣe lọ́wọ́ nínú ẹ̀sùn èké, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ pa aláìṣẹ̀ tàbí olódodo ènìyàn, nítorí Èmi kò ní dá ẹlẹ́bi láre.

  3. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ máa ṣèyíṣọ̀hún bí olóòfófó láàrín àwọn ènìyàn rẹ. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ohunkóhun tí yóò fi ẹ̀mí aládùúgbò rẹ wéwu. Èmi ni Olúwa.

  4. Àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀ mi nínú àrankàn, pé, “Nígbà wo ni yóò kú, ti orúkọ rẹ̀ yóò sì run?”

  5. Nígbàkígbà tí ẹnìkan bá wá wò mí, wọn ń sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn, nígbà tí àyà rẹ̀ bá kó ẹ̀ṣẹ̀ jọ sí ara rẹ̀; nígbà tí ó bá jáde lọ yóò sì máa tàn án kálẹ̀.

  6. Àwọn ọ̀tá mi gbìmọ̀ papọ̀ nípa mi; èmi ni wọ́n ń gbìmọ̀ ibi sí,

  7. wọ́n wí pé, “Ohun búburú ni ó dì mọ́ ọn ṣinṣin àti ní ibi tí ó dùbúlẹ̀ sí, kì yóò dìde mọ́.”

  8. Pàápàá, ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́, ẹni tí mo gbẹ́kẹ̀lé, ẹni tí ó ń jẹ nínú oúnjẹ mi, tí gbé gìgísẹ̀ rẹ̀ sókè sí mi.

  9. “Alábùkún fún ni ẹ̀yin nígbà tí àwọn ènìyàn bá fi àbùkù kàn yín tí wọn bá ṣe inúnibíni sí yín, tiwọn fi ètè èké sọ̀rọ̀ búburú gbogbo sí yín nítorí mi.

  10. Àwọn ọmọ-ogun sì béèrè lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Àti àwa, kí ni àwa ó ṣe?” Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe hùwà ipá sí ẹnikẹ́ni, kí ẹ má sì ṣe ka ẹ̀sùn èké sí ẹnikẹ́ni; kí òwò ọ̀yà yín tó yín.”

  11. Aláìnífẹ̀ẹ́, aláìlèdáríjì, abanijẹ́, aláìlè-kó-aràwọn-níjánu, òǹrorò, aláìnífẹ̀ẹ́ ohun rere,

  12. Bí a bá gàn yín nítorí orúkọ Kristi, ẹni ìbùkún ni yín: nítorí Ẹ̀mí Ògo àti ti Ọlọ́run bà lé yín.