Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Conscience: The blood of Christ alone can purify

9 ẹsẹ · 15 abala

Àwọn ẹsẹ nípa The blood of Christ alone can purify

  1. Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, a kì ìbá tí dẹ́kun àti máa rú wọn, nítorí àwọn ti ń sìn ki ìbá tí ní ìmọ̀ ẹ̀ṣẹ̀, nígbà tí a bá ti wẹ̀ wọ́n mọ́ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.

  2. Ṣùgbọ́n nínú ẹbọ wọ̀nyí ni a ń ṣe ìrántí ẹ̀ṣẹ̀ lọ́dọọdún.

  3. Nítorí ko ṣe é ṣe fún ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù àti ti ewúrẹ́ láti mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò.

  4. Nítorí náà nígbà tí Kristi wá sí ayé, ó wí pé, “Ìwọ kò fẹ́ ẹbọ àti ọrẹ, ṣùgbọ́n ara ni ìwọ ti pèsè fún mi,

  5. ẹbọ sísun àti ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ ni ìwọ kò ní inú dídùn sí.

  6. Nígbà náà ni mo wí pé, ‘Kíyèsi i (nínú ìwé kíká ni a gbé kọ ọ́ nípa ti èmi) mo dé láti ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọ́run.’ ”

  7. Nígbà tí o wí ni ìṣáájú pé, “Ìwọ kò fẹ́ ẹbọ àti ọrẹ àti ẹbọ sísun, àti ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò ni inú dídùn si wọn” (àwọn èyí tí a ń rú gẹ́gẹ́ bí òfin).

  8. Nígbà náà ni ó wí pé, “Kíyèsi i, mo de láti ṣe ìfẹ́ rẹ Ọlọ́run.” Ó mú ti ìṣáájú kúrò, kí a lè fi ìdí èkejì múlẹ̀.

  9. Nípa ìfẹ́ náà ni a ti sọ wá di mímọ́ nípa ẹbọ ti Jesu Kristi fi ara rẹ̀ rú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.