Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Chariot: For war
Àwọn ẹsẹ nípa For war
Nítorí tí wọn kò ṣọ òtítọ́ sí Olúwa. Ṣiṣaki ọba Ejibiti dojúkọ Jerusalẹmu ní ọdún karùn-ún ti ọba Rehoboamu.
Pẹ̀lú ẹgbàá mẹ́fà (12,000) kẹ̀kẹ́ àti ọ̀kẹ́ mẹ́ta (60,000) àwọn ọkùnrin ẹlẹ́ṣin àti àìníye ọ̀wọ́ ogun ti Libia, Sukki àti Kuṣi, tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ láti Ejibiti.
Asà àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ sì di pupa; àwọn ológun wọn sì wọ aṣọ òdòdó. Idẹ tí ó wà lórí kẹ̀kẹ́ ogun ń kọ mọ̀nàmọ́ná ní ọjọ́ tí a bá pèsè wọn sílẹ̀ tán; igi firi ni a ó sì mì tìtì.
Àwọn kẹ̀kẹ́ ogun yóò ya bo àwọn pópónà, wọn yóò sì máa sáré síwá àti sẹ́yìn ní àárín ìgboro. Wọn sì dàbí ètùfù iná; tí ó sì kọ bí i mọ̀nàmọ́ná.