Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Bread: Multitudes miraculously fed by Christ with

7 ẹsẹ · 53 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Multitudes miraculously fed by Christ with

  1. Lẹ́yìn náà, ó wí fún àwọn ènìyàn kí wọ́n jókòó lórí koríko. Lẹ́yìn náà, ó mú ìṣù àkàrà márùn-ún àti ẹja méjì. Ó gbé ojú rẹ̀ sí ọ̀run. Ó béèrè ìbùkún Ọlọ́run lórí oúnjẹ náà, Ó sì bù ú, ó sì fi àkàrà náà fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn láti pín in fún àwọn ènìyàn.

  2. Gbogbo wọn sì jẹ àjẹyó. Lẹ́yìn náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kó àjẹkù jọ, ó kún agbọ̀n méjìlá.

  3. Iye àwọn ènìyàn ni ọjọ́ náà jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ọkùnrin, láìka àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé.

  4. Jesu sì béèrè pé, “Ìṣù àkàrà mélòó ni ẹ̀yin ní?” Wọ́n sì dáhùn pé, “Àwa ní ìṣù àkàrà méje pẹ̀lú àwọn ẹja wẹ́wẹ́ díẹ̀.”

  5. Jesu sì sọ fún gbogbo ènìyàn kí wọn jókòó lórí ilẹ̀.

  6. Òun sì mú ìṣù àkàrà méje náà àti ẹja náà. Ó sì fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run, ó bù wọ́n sì wẹ́wẹ́, ó sì fi wọ́n fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Wọ́n sì pín in fún àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn náà.

  7. Gbogbo wọn jẹ, wọ́n sì yó. Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì ṣa èyí tókù, ẹ̀kún agbọ̀n méje ni èyí tó ṣẹ́kù jẹ́.