Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Avarice: General references

6 ẹsẹ · 2 abala

Àwọn ẹsẹ nípa General references

  1. Lẹ́ẹ̀kan sí i, mo tún rí ohun asán kan lábẹ́ oòrùn.

  2. Ọkùnrin kan ṣoṣo dá wà; kò ní ọmọkùnrin kankan tàbí ẹbí. Kò sí òpin nínú làálàá rẹ̀ gbogbo, síbẹ̀, ọrọ̀ kò tẹ́ ojú rẹ̀ lọ́rùn. Bẹ́ẹ̀ ni kò sì wí pé, “Nítorí ta ni èmí ṣe ń ṣe làálàá, àti wí pé, èétiṣe tí mo fi ń fi ìgbádùn du ara mi?” Eléyìí náà asán ni, iṣẹ́ òsì!

  3. Ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ owó kì í ní owó ànító, ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ sí ọrọ̀ kì í ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú èrè tí ó ń wọlé fún un.

  4. Bí ẹrù bá ti ń pọ̀ sí i, náà ni àwọn tí ó ń jẹ ẹ́ yóò máa pọ̀ sí i Èrè e kí ni wọ́n sì jẹ́ sí ẹni tí ó ni nǹkan bí kò ṣe pé, kí ó máa mú inú ara rẹ dùn nípa rí rí wọn?

  5. Ǹjẹ́ alábojútó yẹ kí ó jẹ́ aláìlẹ́gàn, ọkọ aya kan, olùṣọ̀ràn, aláìrékọjá, oníwà rere, olùfẹ́ àlejò ṣíṣe, ẹni tí ó lè ṣe olùkọ́.

  6. Kí ó má jẹ́ ọ̀mùtí, tàbí oníjàgídíjàgan, tàbí olójúkòkòrò, bí kò ṣe onísùúrù, kí ó má jẹ́ oníjà, tàbí olùfẹ́ owó.