Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Alamoth: Inscription to Psalm 46:1-11

11 ẹsẹ · 2 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Inscription to Psalm 46:1-11

  1. Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Gẹ́gẹ́ bí ti alamoti. Orin. Ọlọ́run ni ààbò àti agbára wa ó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ ní ìgbà ìpọ́njú.

  2. Nítorí náà àwa kì yóò bẹ̀rù, bí a tilẹ̀ ṣí ayé ní ìdí, tí òkè sì ṣubú sínú Òkun.

  3. Tí omi rẹ̀ tilẹ̀ ń hó tí ó sì ń mì tí àwọn òkè ńlá tilẹ̀ ń mì pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ̀. Sela.

  4. Odò ńlá kan wà tí ṣíṣàn rẹ̀ mú inú ìlú Ọlọ́run dùn, ibi mímọ́, níbi ti Ọ̀gá-ògo ń gbé.

  5. Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀, kò ní yẹ̀: Ọlọ́run yóò ràn án lọ́wọ́ ní kùtùkùtù òwúrọ̀.

  6. Àwọn orílẹ̀-èdè ń bínú, àwọn ilẹ̀ ọba ṣubú, ó gbé ohun rẹ̀ sókè, ayé yọ̀.

  7. Olúwa àwọn ọmọ-ogun wà pẹ̀lú wa, Ọlọ́run Jakọbu ni ààbò wa.

  8. Ẹ wá wo iṣẹ́ Olúwa irú ahoro tí ó ṣe ní ayé.

  9. O mú ọ̀tẹ̀ tán de òpin ilẹ̀ ayé ó ṣẹ́ ọrun, ó sì gé ọ̀kọ̀ sí méjì ó fi kẹ̀kẹ́ ogun jóná.

  10. Ẹ dúró jẹ́ẹ́, kí ẹ sì mọ̀ pé èmi ní Ọlọ́run. A ó gbé mi ga nínú àwọn orílẹ̀-èdè, a ó gbé mi ga ní ayé.

  11. Olúwa àwọn ọmọ-ogun wà pẹ̀lú wa; Ọlọ́run Jakọbu sì ni ààbò wa.