Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Access to God: Saints earnestly seek

6 ẹsẹ · 18 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Saints earnestly seek

  1. Ohun kan ni mo béèrè lọ́dọ̀ Olúwa, òhun ni èmi yóò máa wá kiri: kí èmi kí ó le wà ní ilé Olúwa ní ọjọ́ ayé mi gbogbo, kí èmi: kí ó le kíyèsi ẹwà Olúwa, kí èmi kí ó sì máa wà ní tẹmpili rẹ̀.

  2. Fún adarí orin. Maskili ti àwọn ọmọ Kora. Bí àgbọ̀nrín ti ń mí hẹlẹ sí ipa odò omi, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mi ń mí hẹlẹ sí ọ Ọlọ́run.

  3. Òùngbẹ Ọlọ́run ń gbẹ ọkàn mi, fún Ọlọ́run alààyè. Nígbà wo ni èmi ó lọ bá Ọlọ́run?

  4. Rán ìmọ́lẹ̀ àti òtítọ́ rẹ jáde, jẹ́ kí wọn ó máa dáàbò bò mí; jẹ́ kí wọn mú mi wá sí òkè mímọ́ rẹ, sí ibi tí ìwọ ń gbé.

  5. Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti gittiti. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu. Ibùgbé rẹ̀ ti lẹ́wà tó, Olúwa àwọn ọmọ-ogun!

  6. Ọkàn mi ń ṣàfẹ́rí nítòótọ́ ó tilẹ̀ pòǹgbẹ fún àgbàlá Olúwa àyà mi àti ara mi ń kọrin ayọ̀ sí Ọlọ́run alààyè.