Fò sí àkóónú

Jezaniah

4 ẹsẹ · 1 ọmọ ẹbí

A tún mọ̀ ọ́n sí: Jaazaniah, Azariah

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Jezaniah

  1. Nígbà tí gbogbo àwọn olórí ogun àti àwọn ọkùnrin wọn gbọ́ pé ọba Babeli ti yan Gedaliah gẹ́gẹ́ bí baálẹ̀, wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Gedaliah ni Mispa. Iṣmaeli ọmọ Netaniah, Johanani ọmọ Karea, Seraiah ọmọ Tanhumeti ará Netofa, Jaaṣaniah ọmọ ará Maakati, àti àwọn ọkùnrin wọn.

  2. wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Gedaliah ní Mispa; Iṣmaeli ọmọkùnrin Netaniah, Johanani àti Jonatani ọmọkùnrin ti Karea, Seraiah ọmọkùnrin Tanhumeti tí í ṣe ọmọkùnrin Efai ará Netofa àti Jesaniah ọmọkùnrin Maakati àti àwọn ènìyàn wọn.

  3. Nígbà náà ní gbogbo àwọn olórí ogun àti Johanani ọmọkùnrin Karea àti Jesaniah ọmọkùnrin Hoṣaiah àti kékeré títí dé orí ẹni ńlá wá.

  4. Asariah ọmọ Hoṣaiah àti Johanani ọmọ Karea, àti gbogbo àwọn agbéraga ọkùnrin sọ fún Jeremiah pé, “Ìwọ ń pa irọ́! Olúwa Ọlọ́run wa kò rán ọ láti sọ pé, ‘Ẹ má lọ sí Ejibiti láti ṣàtìpó níbẹ̀.’