Hananiah
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Hananiah
Ní oṣù karùn-ún ní ọdún kan náà, ọdún kẹrin ní ìbẹ̀rẹ̀ ìṣèjọba Sedekiah ọba Juda, wòlíì Hananiah ọmọ Assuri, tí ó wá láti Gibeoni, sọ fún mi ní ilé Olúwa tí ó wà ní iwájú àwọn àlùfáà àti gbogbo ènìyàn:
Wòlíì Jeremiah wí fún wòlíì Hananiah ní iwájú ọmọ àlùfáà àti àwọn ènìyàn tí wọ́n dúró ní ilé Olúwa.
Wòlíì Hananiah gbé àjàgà ọrùn wòlíì Jeremiah kúrò, ó sì fọ́ ọ.
Hananiah sọ níwájú gbogbo ènìyàn wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Bákan náà ni Èmi yóò fọ́ àjàgà ọrùn Nebukadnessari, ọba Babeli láàrín ọdún méjì.’ ” Wòlíì Jeremiah sì bá ọ̀nà tirẹ̀ lọ.
Láìpẹ́ ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wòlíì wá lẹ́yìn ìgbà tí wòlíì Hananiah ti gbé àjàgà kúrò ní ọrùn wòlíì Jeremiah wí pé:
“Lọ sọ fún Hananiah, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí, ìwọ ti wó àjàgà onígi, ṣùgbọ́n ní ààyè wọn, wà á bá àjàgà onírin.
Wòlíì Jeremiah sọ fún wòlíì Hananiah pé, “Gbọ́ ọ, Hananiah! Olúwa kò rán ọ, síbẹ̀, ìwọ jẹ́ kí orílẹ̀-èdè yìí gba irọ́ gbọ́.
Ní oṣù keje ọdún yìí ni Hananiah wòlíì kú.