Fò sí àkóónú
Titu 3:12-15

Àwọn ìtọ́ni àti ìkíni ìkẹyìn

Titu 3:12-15
12
Ní kété tí mo bá ti rán Artema tàbí Tikiku sí ọ, sa gbogbo ipá rẹ láti tọ̀ mí wá ní Nikopoli, nítorí mo ti pinnu láti lo ìgbà òtútù mi níbẹ̀.
13
Sa gbogbo agbára rẹ láti ran Senasi amòfin àti Apollo lọ́wọ́ nínú ìrìnàjò wọn. Rí i dájú pé wọ́n ní ohun gbogbo tí wọn nílò.
14
Àwọn ènìyàn nílò láti kọ́ bí a tí ń fi ara ẹni jì sí iṣẹ́ rere kí wọn ba à le pèsè ohun kòsémánìí fún ara wọn, nípa èyí, wọn kì yóò jẹ́ aláìléso.
15
Gbogbo àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ mi kí ọ. Bá mi kí àwọn tí ó fẹ́ wa nínú ìgbàgbọ́. Kí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú gbogbo yín.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options