Romu 9:1-5
1
Òtítọ́ ni èmi ń sọ nínú Kristi, èmi kò ṣèké, ọkàn mi sì ń jẹ́ mi ní ẹ̀rí nínú Ẹ̀mí Mímọ́.
2
Pé mo ní ìbìnújẹ́ púpọ̀, àti ìkáàánú ìgbà gbogbo ni ọkàn mi.
3
Nítorí mo fẹ́rẹ lè gbàdúrà pé kí èmi tìkára mi kúrò lọ́dọ̀ Kristi nítorí àwọn ará mi, àwọn ìbátan mi nípa ti ara.
4
Àwọn ẹni tí i ṣe Israẹli; tí àwọn ẹni tí ìsọdọmọ í ṣe, àti ògo, àti májẹ̀mú, àti ìfúnilófin, àti ìsìn Ọlọ́run, àti àwọn ìlérí.
5
Tí ẹni tí àwọn Baba í ṣe, àti láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹni tí Kristi ti wá nípa ti ara, ẹni tí ó borí ohun gbogbo, Ọlọ́run olùbùkún láéláé. Àmín.
Settings