Skip to content
Ìfihàn 9:13-21

Ìfihàn 9:13-21

13
Angẹli kẹfà si fọn ìpè rẹ̀, mo sì gbọ́ ohùn kan láti ibi ìwo mẹ́rin pẹpẹ wúrà wá, tí ń bẹ níwájú Ọlọ́run.
14
Òun wí fún angẹli kẹfà náà tí o ni ìpè náà pé, “Tú àwọn angẹli mẹ́rin náà sílẹ̀ tí a dè lẹ́bàá odò ńlá Eufurate!”
15
A sì tú àwọn angẹli mẹ́rin náà sílẹ̀, tí a ti pèsè tẹ́lẹ̀ fún wákàtí náà, àti ọjọ́ náà, àti oṣù náà, àti ọdún náà, láti pa ìdámẹ́ta ènìyàn.
16
Iye ogún àwọn ẹlẹ́ṣin sì jẹ́ àádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà igba, mo sì gbọ́ iye wọn.
17
Báyìí ni mo sì rí àwọn ẹṣin náà ní ojúran, àti àwọn tí o gùn wọ́n, wọ́n ni ìgbàyà aláwọ̀ iná, àti ti jakinti, àti ti sulfuru, orí àwọn ẹṣin náà sì dàbí orí àwọn kìnnìún; àti láti ẹnu wọn ni iná, àti èéfín, àti sulfuru tí ń jáde.
18
Nípa ìyọnu mẹ́ta wọ̀nyí ni a tí pa ìdámẹ́ta ènìyàn, nípa iná, àti nípa èéfín, àti nípa sulfuru tí o ń tí ẹnu wọn jáde.
19
Nítorí pé agbára àwọn ẹṣin náà ń bẹ ní ẹnu wọn àti ní ìrù wọn: nítorí pé ìrù wọn dàbí ejò, wọn sì ní orí, àwọn wọ̀nyí ni wọn sì fi ń pa ni lára.
20
Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ìyókù tí a kò sì ti ipa ìyọnu wọ̀nyí pa, kò sì ronúpìwàdà iṣẹ́ ọwọ́ wọn, kí wọn má ṣe sin àwọn ẹ̀mí èṣù àti ère wúrà, àti ti fàdákà, àti ti idẹ, àti òkúta, àti ti igi mọ́: àwọn tí kò lè ríran, tàbí kí wọn gbọ́rọ̀, tàbí kí wọn rìn.
21
Bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ronúpìwàdà ìwà ìpànìyàn wọn, tàbí oṣó wọn tàbí àgbèrè wọn, tàbí olè wọn.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options