Ìfihàn 5:1-7
1
Mo sì rí i ni ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà, ìwé kan ti a kọ nínú àti lẹ́yìn, ti a sì fi èdìdì méje dí.
2
Mó sì rí angẹli alágbára kan, ó ń fi ohùn rara kéde pé, “Ta ni ó yẹ láti ṣí ìwé náà, àti láti tu èdìdì rẹ̀?”
3
Kò sì ṣí ẹni kan ní ọ̀run, tàbí lórí ilẹ̀ ayé, tàbí nísàlẹ̀ ilẹ̀, tí ó le ṣí ìwé náà, tàbí ti o lè wo inú rẹ̀.
4
Èmi sì sọkún gidigidi, nítorí tí a kò ri ẹnìkan tí o yẹ láti sí i àti láti ka ìwé náà, tàbí láti wo inú rẹ̀.
5
Ọ̀kan nínú àwọn àgbà náà sì wí fún mi pé, “Má ṣe sọkún: kíyèsi i, kìnnìún ẹ̀yà Juda, Gbòǹgbò Dafidi, tí borí láti ṣí ìwé náà, àti láti tú èdìdì rẹ̀ méjèèje.”
6
Mo sì rí Ọ̀dọ́-Àgùntàn ni àárín ìtẹ́ náà, àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, àti ni àárín àwọn àgbà náà, Ọ̀dọ́-àgùntàn kan dúró bí èyí tí a ti pa, ó ní ìwo méje àti ojú méje, tí o jẹ́ Ẹ̀mí méje tí Ọlọ́run, tí a rán jáde lọ sì orí ilẹ̀ ayé gbogbo.
7
Ó sì wá, o sì gbà á ìwé náà ni ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà.
Settings