Ìfihàn 2:1-7
1
“Sí angẹli ìjọ ní Efesu kọ̀wé: Nǹkan wọ̀nyí ní ẹni tí ó mú ìràwọ̀ méje náà ni ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ wí, ẹni tí ń rìn ní àárín ọ̀pá wúrà fìtílà méje.
2
Èmi mọ iṣẹ́ rẹ, àti làálàá rẹ, àti ìfaradà rẹ, àti bí ara rẹ kò ti gba àwọn ẹni búburú, àti bí ìwọ sì ti dán àwọn tí ń pe ara wọn ní aposteli, tí wọ́n kì í sì í ṣe bẹ́ẹ̀ wo, tí ìwọ sì rí pé èké ni wọ́n,
3
tí ìwọ sì faradà ìyà, àti nítorí orúkọ mi tí ó sì rọ́jú, tí àárẹ̀ kò sì mú ọ.
4
Síbẹ̀ èyí ni mo rí wí sí ọ, pé, ìwọ ti fi ìfẹ́ ìṣáájú rẹ sílẹ̀.
5
Rántí ibi tí ìwọ ti gbé ṣubú! Ronúpìwàdà, kí ó sì ṣe iṣẹ́ ìṣáájú; bí kò sì ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ó sì tọ̀ ọ́ wá, èmi ó sì ṣí ọ̀pá fìtílà rẹ̀ kúrò ní ipò rẹ̀, bí kò ṣe bí ìwọ bá ronúpìwàdà.
6
Ṣùgbọ́n èyí ni ìwọ ní, pé ìwọ kórìíra ìṣe àwọn Nikolatani, èyí tí èmi pẹ̀lú sì kórìíra.
7
Ẹni tí ó bá ní etí kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ. Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun ni èmi yóò fi èso igi ìyè nì fún jẹ, tí ń bẹ láàrín Paradise Ọlọ́run.
Settings