Saamu 5:1-8
1
Fún adarí orin. Fún ohun èlò orin fífọn. Saamu ti Dafidi. Fi etí sí ọ̀rọ̀ mi, Olúwa, kíyèsi àròyé mi.
2
Fi etí sílẹ̀ sí igbe mi fún ìrànlọ́wọ́, ọba mi àti Ọlọ́run mi, nítorí ìwọ ni mo gba àdúrà sí.
3
Ní òwúrọ̀, Olúwa, ìwọ yóò gbọ́ ohùn mi; ní òwúrọ̀, èmi yóò gbé ẹ̀bẹ̀ mi sí iwájú rẹ̀ èmi yóò sì dúró ní ìrètí.
4
Nítorí ìwọ kì í ṣe Ọlọ́run tí ó ní inú dídùn sí búburú; bẹ́ẹ̀ ni ẹni ibi kò le è bá ọ gbé.
5
Àwọn agbéraga kò le è dúró níwájú rẹ̀. Ìwọ kórìíra gbogbo àwọn aṣebi;
6
ìwọ yóò pa àwọn tí ń ṣe èké run. Apani àti ẹni ẹ̀tàn ènìyàn ni Olúwa yóò kórìíra.
7
Ṣùgbọ́n èmi, nípa títóbi àánú rẹ̀, èmi yóò wá sínú ilé rẹ̀; ní tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ni èmi yóò tẹríba sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ̀.
8
Tọ́ mi, Olúwa, nínú òdodo rẹ, nítorí àwọn ọ̀tá mi, mú ọ̀nà rẹ tọ́ níwájú mi.
Settings