Saamu 35:11-18
11
Àwọn ẹlẹ́rìí èké dìde; wọ́n ń bi mi ní ohun tí èmi kò mọ̀.
12
Wọ́n fi búburú san ìre fún mi; láti sọ ọkàn mi di òfo.
13
Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi ni, nígbà tí wọn ń ṣe àìsàn, mo wọ aṣọ ọ̀fọ̀; mo fi àwẹ̀ pọ́n ara mi lójú. Mo gba àdúrà pẹ̀lú ìtẹríba ní oókan àyà mi;
14
èmí ń lọ kiri bí ẹni ń ṣọ̀fọ̀ bí i ẹni wí pé fún ọ̀rẹ́ tàbí ẹ̀gbọ́n mi ni. Èmí tẹríba nínú ìbànújẹ́ bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ìyà rẹ̀.
15
Ṣùgbọ́n nínú ìkọ̀sẹ̀ mi wọ́n sì yọ̀, wọ́n sì kó ara wọn jọ; wọ́n kó ara wọn jọ sí mi; àní àwọn tí èmi kò mọ̀. Wọ́n fà mí ya wọ́n kò sì dákẹ́.
16
Bí àwọn àgàbàgebè tí ń ṣe ẹlẹ́yà ní àpèjẹ wọ́n pa eyín wọn keke sí mi.
17
Yóò ti pẹ́ tó Olúwa, tí ìwọ yóò máa wò wọ́n lọ? Yọ mí kúrò nínú ìparun wọn, àní ẹ̀mí ì mi kúrò lọ́wọ́ kìnnìún.
18
Nígbà náà ni èmi yóò ṣọpẹ́ fún Ọ nínú àjọ ńlá; èmi yóò máa yìn Ọ́ ní àwùjọ ọ̀pọ̀ ènìyàn.
Settings