Skip to content
Òwe 24:23-29

Òwe 24:23-29

23
Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú tún jẹ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n: láti ṣe ojúsàájú níbi ìdájọ́ kò dára rárá.
24
Ẹnikẹ́ni tí ó wí fún ẹlẹ́bi pé, “Ìwọ lo jàre,” àwọn ènìyàn yóò ṣẹ́ èpè fún un àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì kọ̀ ọ́.
25
Ṣùgbọ́n yóò dára fún àwọn tí ń dá ẹlẹ́bi lẹ́bi, ọ̀pọ̀ ìbùkún yóò sì wá sórí wọn.
26
Ìdáhùn òtítọ́ dàbí ìfẹnukoni ní ẹnu.
27
Parí gbogbo iṣẹ́ ajé rẹ sì rí i pé oko rẹ ti ṣe dáradára; lẹ́yìn náà kọ́ ilé rẹ.
28
Má ṣe rojọ́ èké mọ́ aládùúgbò rẹ láìnídìí, tàbí kí o fi ètè rẹ tannijẹ.
29
Má ṣe wí pé, “Èmi yóò ṣe é fún un gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe fún mi; Èmi yóò san ohun tí ó ṣe fún mi padà fún un.”
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options