Fò sí àkóónú
Numeri 35:16-24

Numeri 35:16-24

16
“ ‘Bí ọkùnrin kan bá fi ohun èlò irin lu ènìyàn tí ó kú, apànìyàn ni, pípa ni a ó pa, apànìyàn náà.
17
Tàbí tí ènìyàn bá mú òkúta tí ó lè pa ènìyàn lọ́wọ́ tí ó sì fi lu ènìyàn, tí ó sì kú, apànìyàn ni, pípa ni a ó pa apànìyàn náà.
18
Tàbí tí ènìyàn bá mú ohun èlò igi ní ọwọ́ rẹ̀ tí ó sì lẹ̀ ẹ́ pa ènìyàn, tí ó sì fi lu ènìyàn, tí ó sì kú, apànìyàn ni; pípa ní a ó pa apànìyàn náà.
19
Olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ yóò pa apànìyàn náà; tí ó bá bá a, yóò pa á.
20
Tí ẹnikẹ́ni tí ó bá ń yan odì pẹ̀lú ìríra tí ẹlòmíràn tàbí ju nǹkan sí i pẹ̀lú èrò, tí ó sì kú.
21
Tàbí pẹ̀lú ìjà gbangba lù ú pẹ̀lú ìkùùkuu tí ó sì kú, pípa ni a ó pa ẹni bẹ́ẹ̀; apànìyàn ni. Olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ yóò pa apànìyàn náà tí ó bá bá a.
22
“ ‘Ṣùgbọ́n bí ó bá fi nǹkan gún un lójijì láìṣọ̀ta, tàbí tí ó sọ ohunkóhun lù ú láìmọ̀-ọ́n-mọ̀ ṣe
23
tàbí, láìri, ju òkúta sí tí ó lè pa á, tí ó sì kú, nígbà tí kì í ṣe ọ̀tá rẹ̀, láti ṣe é léṣe.
24
Àwọn àpéjọ gbọdọ̀ dájọ́ láàrín rẹ̀ àti olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Reading Width 45 chars

Options