Matiu 19:3-12
3
Àwọn Farisi wá sọ́dọ̀ rẹ̀ láti dán an wò. Wọ́n bi í pé, “Ǹjẹ́ ó tọ̀nà fún ọkùnrin láti kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ nítorí ohunkóhun?”
4
Ó dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ẹyin kò ti kà á pé ‘ẹni tí ó dá wọn ní ìgbà àtètèkọ́ṣe, Ọlọ́run dá wọn ni ti akọ ti abo.’
5
Ó sì wí fún un pé, ‘Nítorí ìdí èyí ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, òun yóò sì dàpọ̀ mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan.’
6
Wọn kì í túnṣe méjì mọ́, ṣùgbọ́n ara kan. Nítorí náà, ohun tí Ọlọ́run bá ti so ṣọ̀kan, kí ẹnikẹ́ni má ṣe yà wọ́n.”
7
Wọ́n bi í pé: “Kí ni ìdí tí Mose fi pàṣẹ pé, ọkùnrin kan lè kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ nípa fífún un ní ìwé ìkọ̀sílẹ̀?”
8
Jesu dáhùn pé, “Nítorí líle àyà yín ni Mose ṣe gbà fún yín láti máa kọ aya yín sílẹ̀. Ṣùgbọ́n láti ìgbà àtètèkọ́ṣe wá, kò rí bẹ́ẹ̀.
9
Mo sọ èyí fún yín pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, láìṣe pé nítorí àgbèrè, tí ó bá sì fẹ́ ẹlòmíràn, ó ṣe panṣágà.”
10
Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Bí ọ̀rọ̀ bá rí báyìí láàrín ọkọ àti aya, kó ṣàǹfààní fún wa láti gbé ìyàwó.”
11
Jesu dáhùn pé, “Gbogbo ènìyàn kọ́ ló lé gba ọ̀rọ̀ yìí, bí kò ṣe iye àwọn tí a ti fún.
12
Àwọn mìíràn jẹ́ akúra nítorí bẹ́ẹ̀ ní a bí wọn, àwọn mìíràn ń bẹ tí ènìyàn sọ wọn di bẹ́ẹ̀; àwọn mìíràn kọ̀ láti gbé ìyàwó nítorí ìjọba ọ̀run. Ẹni tí ó bá lè gbà á kí ó gbà á.”
Settings