Skip to content
Marku 2:5

Marku 2:5

Ń ṣàfihàn ẹsẹ 5 pẹ̀lú àyíká ọ̀rọ̀ tó yí i ká.
2
Láìpẹ́, ogunlọ́gọ̀ ènìyàn ti kún ilé tí ó dé sí tó bẹ́ẹ̀ tí inú ilé àti ẹ̀yìn ìlẹ̀kùn ní ìta kò gba ẹyọ ẹnìkan mọ́, ó sì wàásù ọ̀rọ̀ náà sí wọn.
3
Àwọn ọkùnrin kan wá, wọ́n gbé arọ tọ̀ ọ́ wá, ẹni tí ọkùnrin mẹ́rin gbé.
4
Nígbà tí wọn kò sì le dé ọ̀dọ̀ Jesu, nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn, wọ́n dá òrùlé ilé lu ní ọ̀gangan ibi tí Jesu wà. Wọ́n sì sọ ọkùnrin arọ náà kalẹ̀ ti òun ti àkéte rẹ̀ níwájú Jesu.
5
Nígbà tí Jesu sì rí ìgbàgbọ́ wọn, ó sọ fún arọ náà pé, “Ọmọ, a dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”
6
Ṣùgbọ́n díẹ̀ nínú àwọn olùkọ́ òfin tó jókòó níbẹ̀ sọ fún ara wọn pé,
7
“Èéṣe ti ọkùnrin yìí fi sọ̀rọ̀ báyìí? Ó ń sọ̀rọ̀-òdì. Ta ni ó lè darí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni bí ko ṣe Ọlọ́run nìkan?”
8
Lójúkan náà bí Jesu tí wòye nínú ọkàn rẹ̀ pé wọn ń gbèrò bẹ́ẹ̀ ní àárín ara wọn, ó wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yìn fi ń ro nǹkan wọ̀nyí nínú ọkàn yín?
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Reading Width 90 chars

Options