Luku 20:1-15
1
Ní ọjọ́ kan, bí ó ti ń kọ́ àwọn ènìyàn ní tẹmpili tí ó sì ń wàásù ìyìnrere, àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé, pẹ̀lú àwọn àgbàgbà dìde sí i.
2
Wọ́n sì wí fún un pé, “Sọ fún wa, àṣẹ wo ni ìwọ fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí? Tàbí ta ni ó fún ọ ní àṣẹ yìí?”
3
Ó sì dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Èmi pẹ̀lú yóò sì bi yín léèrè ọ̀rọ̀ kan; ẹ sì fi ìdáhùn fún mi.
4
Ìtẹ̀bọmi Johanu, láti ọ̀run wá ni tàbí láti ọ̀dọ̀ ènìyàn?”
5
Wọ́n sì bá ara wọn gbèrò pé, “Bí àwa bá wí pé, ‘Láti ọ̀run wá ni,’ òun yóò wí pé, ‘Èéṣe tí ẹ̀yin kò fi gbà á gbọ́?’
6
Ṣùgbọ́n bí àwa bá sì wí pé, ‘Láti ọ̀dọ̀ ènìyàn,’ gbogbo ènìyàn ni yóò sọ wá ní òkúta, nítorí wọ́n gbàgbọ́ pé, wòlíì ni Johanu.”
7
Wọ́n sì dáhùn wí pé, “Àwa kò mọ̀ ibi tí ó ti wá.”
8
Jesu sì wí fún wọn pé, “Ǹjẹ́ èmi kì yóò wí fún yín àṣẹ tí èmi fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí.”
9
Nígbà náà ni ó bẹ̀rẹ̀ sí í pa òwe yìí fún àwọn ènìyàn pé, “Ọkùnrin kan gbin ọgbà àjàrà kan, ó sì fi ṣe àgbàtọ́jú fún àwọn olùṣọ́gbà, ó sì lọ sí àjò fún ìgbà pípẹ́.
10
Nígbà tí ó sì tó àkókò, ó rán ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ kan sí àwọn olùṣọ́gbà náà, kí wọn lè fún un nínú èso ọgbà àjàrà náà, ṣùgbọ́n àwọn alágbàtọ́jú lù ú, wọ́n sì rán an padà lọ́wọ́ òfo.
11
Ó sì tún rán ọmọ ọ̀dọ̀ mìíràn, wọ́n sì lù ú pẹ̀lú, wọ́n sì jẹ ẹ́ ní yà, wọ́n sì rán an padà lọ́wọ́ òfo.
12
Ó sì tún rán ẹ̀kẹta: wọ́n sì sá a lọ́gbẹ́ pẹ̀lú, wọ́n sì tì í jáde.
13
“Nígbà náà ni Olúwa ọgbà àjàrà wí pé, ‘Èwo ni èmi ó ṣe? Èmi ó rán ọmọ mi àyànfẹ́ lọ: bóyá nígbà tí wọ́n bá rí i, wọn yóò bu ọlá fún un.’
14
“Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn alágbàtọ́jú náà rí i, wọ́n bá ara wọn gbèrò pé, ‘Èyí ni àrólé; ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á, kí ogún rẹ̀ lè jẹ́ ti wa.’
15
Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì tì í jáde sẹ́yìn ọgbà àjàrà, wọ́n sì pa á. “Ǹjẹ́ kín ni olúwa ọgbà àjàrà náà yóò ṣe sí wọn?
Settings