Luku 17:11-16
11
Ó sì ṣe, bí ó ti ń lọ sí Jerusalẹmu, ó kọjá láàrín Samaria Galili.
12
Bí ó sì ti ń wọ inú ìletò kan lọ, àwọn ọkùnrin adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá pàdé rẹ̀, wọ́n dúró ní òkèrè,
13
wọ́n sì kígbe sókè wí pé, “Jesu, Olùkọ́, ṣàánú fún wa.”
14
Nígbà tí ó rí wọn, ó wí fún wọn pé, “Ẹ lọ í fi ara yín hàn fún àwọn àlùfáà.” Ó sì ṣe, bí wọ́n ti ń lọ, wọ́n sì di mímọ́.
15
Nígbà tí ọ̀kan nínú wọn rí i pé a mú òun láradá ó padà, ó sì fi ohùn rara yin Ọlọ́run lógo.
16
Ó sì wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀, ó ń dúpẹ́ ní ọwọ́ rẹ̀: ará Samaria ni òun í ṣe.
Settings