Skip to content
Lefitiku 15:2-15

Lefitiku 15:2-15

2
“Ẹ bá àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀, kí ẹ wí fún wọn pé, ‘Bí ìsunjáde bá ń jáde lára ọkùnrin kan lójú ara, ìsunjáde náà jẹ́ àìmọ́.
3
Yálà ó ń jáde léraléra tàbí ó dúró, èyí yóò sọ ọ́ di aláìmọ́. Báyìí ni ìsunjáde rẹ̀ ṣe le è sọ ọ́ di aláìmọ́:
4
“ ‘Gbogbo ibùsùn tí irú ẹni tí ó ní ìsunjáde náà bá sùn di àìmọ́.
5
Bí ẹnikẹ́ni bá fi ara kan ibùsùn rẹ̀, ó gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀. Yóò sì wà ní ipò àìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.
6
Ẹnikẹ́ni tí ó bá jókòó lórí ohunkóhun tí ọkùnrin tí ó ní ìsunjáde bá jókòó le gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, kí ó sì wà láìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
7
“ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan ọkùnrin náà tí ó ní ìsunjáde gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóò sì di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
8
“ ‘Bí ẹni tí ó ní ìsunjáde bá tu itọ́ sí ẹni tí ó mọ́ lára, ẹni tí ó mọ́ náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀, yóò sì wà ní ipò àìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
9
“ ‘Gàárì ẹranko tí ẹni náà bá gùn yóò di àìmọ́.
10
Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan ohunkóhun tí ó wà lábẹ́ ọkùnrin náà di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá mú irú nǹkan bẹ́ẹ̀ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó wẹ ara rẹ̀. Yóò sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
11
“ ‘Ẹnikẹ́ni tí ọkùnrin tí ó ní ìsunjáde ní ara rẹ̀ bá fi ara kàn láìfi omi fọ ọwọ́ rẹ̀, gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀. Yóò sì wà ní ipò àìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.
12
“ ‘Ìkòkò amọ̀ tí ọkùnrin náà bá fọwọ́ kàn ni kí ẹ fọ́, gbogbo ohun èlò igi tí ó fọwọ́ kàn ni kí ẹ fi omi sàn.
13
“ ‘Ẹnikẹ́ni tí a bá wẹ̀nù kúrò nínú ìsunjáde rẹ̀ gbọdọ̀ ka ọjọ́ méje fún àwọn ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́: kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì fi omi wẹ ara rẹ̀, yóò sì di mímọ́.
14
Ní ọjọ́ kẹjọ kí ó mú àdàbà méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì, kí ó sì wá sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé níwájú Olúwa, kí ó sì kó wọn fún àlùfáà.
15
Kí àlùfáà fi wọ́n rú ẹbọ: ọ̀kan fún ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ọrẹ ẹbọ sísun níwájú Olúwa ní ipò ọkùnrin náà nítorí ìsunjáde rẹ̀.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Reading Width 45 chars

Options