Joṣua 11:3
Ń ṣàfihàn ẹsẹ 3 pẹ̀lú àyíká ọ̀rọ̀ tó yí i ká.
1
Nígbà tí Jabini ọba Hasori gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ó ránṣẹ́ sí Jobabu ọba Madoni, sí ọba Ṣimroni àti Akṣafu,
2
àti sí àwọn ọba ìhà àríwá tí wọ́n wà ní orí òkè ní aginjù, gúúsù ti Kinnereti, ní ẹsẹ̀ òkè ìwọ̀-oòrùn àti ní Nafoti Dori ní ìwọ̀-oòrùn;
3
sí àwọn ará Kenaani ní ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn; sí àwọn Amori, Hiti, Peresi àti Jebusi ní orí òkè; àti sí àwọn Hifi ní ìsàlẹ̀ Hermoni ní agbègbè Mispa.
4
Wọ́n sì jáde pẹ̀lú gbogbo ogun wọn àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ogun ńlá, wọ́n sì pọ̀, gẹ́gẹ́ bí iyanrìn etí òkun.
5
Gbogbo àwọn ọba yìí pa ọmọ-ogun wọn pọ̀, wọ́n sì pa ibùdó sí ibi omi Meromu láti bá Israẹli jà.
6
Olúwa sì sọ fún Joṣua pé, “Má ṣe bẹ̀rù wọn, nítorí ní àkókò yìí ní ọ̀la, gbogbo wọn ni èmi yóò fi lé Israẹli lọ́wọ́ ní pípa. Ìwọ yóò já iṣan ẹ̀yìn ẹṣin wọn, ìwọ yóò sì sun kẹ̀kẹ́ ogun wọn.”
Settings